1. Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan,nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn!Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrin àwọn orílẹ̀ èdè,tí ó wà nípò opó,Ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọba bìnrin láàrin ìlúni ó padà di ẹrú.
2. Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sunkún kíkoròpẹ̀lú omijé tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀.Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún.Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀wọ́n ti di alátakò rẹ̀.
3. Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú,Júdà lọ sí àjòÓ tẹ̀dó láàrin àwọn orílẹ̀ èdè,ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi.Àwọn tí ó ń tẹ̀le ká a mọ́ibi tí kò ti le sá àṣálà.