Ékísódù 37:20-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Lára ọ̀pá fìtílà náà ni a se kọ́ọ̀bù mẹ́rin bí ìtànná alímóndì, ìrùdí rẹ̀ àti ìtànná rẹ̀:

21. Ìrùdí kan níṣàlẹ̀ ẹ̀ka méjì jáde lará ọ̀pá fìtílà náà, ìrùdí kejì níṣàlẹ̀ èkejì, àti ìrùdí kẹ́ta níṣàlẹ̀ ìrùdí ìkẹta-ẹ̀ka mẹ́fà lò wà lára gbogbo rẹ̀.

22. Ìrùdí náà àti ẹ̀ka wọn jẹ́ bákan náà, ó lù ú jáde ní kìkì wúrà.

23. Ó se fìtílà méje rẹ̀, pẹ̀lú àlùmágàjí àti àwo rẹ̀ kìkì wúrà ni.

24. Ó sì se ọ̀pá fìtílà náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ láti ara talẹ́ńtì kan tí ó jẹ́ kìkì wúrà.

25. Igi kaṣíá ní ó fi ṣe pẹpẹ tùràrí náà. Igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ jẹ́ déédé, gígùn rẹ̀ jẹ ìdajì mítà, fífẹ̀ rẹ̀ náà jẹ́ ìdajì mítà àti gíga rẹ̀ sì jẹ́ mítà kan-ìwo rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà.

26. Kìkì wúrà ni ó fi bo orí rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀, ó sì fi ìgbátí wúrà yìí ká.

27. Ó se òrùka wúrà méjì sí ìṣàlẹ̀ ìgbátí náà méjì ní ọ̀kánkán ara wọn láti gbá òpó náà mú láti máa fi gbé e.

28. Ó ṣe òpó igi kaṣíá, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú u wúrà.

29. Ó sì tún ṣe òróró mímọ́ ìtasórí àti kìkì òórùn dídùn tùràrí-iṣẹ́ àwọn tí ń ṣe nǹkan olóòórùn.

Ékísódù 37