17. Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́nni ori òkè ti ìwọ jogún;Ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa.Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbékalẹ̀, Olúwa.
18. Olúwa yóò jọbaláé àti láéláé.”
19. Nígbà ti ẹsin Fáráò, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ wọ inú òkun, Olúwa mú kí omi òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la òkun kọjá.
20. Míríámù wòlíì obìnrin, arábìnrin Árónì, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, àwọn obìnrin ti ó tẹ̀lé pẹ̀lú mú ohun èlò orin wọ́n sì ń jó.
21. Míríámà kọrin sí wọn báyìí pé:“Ẹ kọrin sí OlúwaNítorí òun ni ológo jùlọẸṣin àti ẹni tí ó gùn únNi òun bi subú sínú òkun.”
22. Nígbà náà ni Mósè ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde láti òkun pupa lọ sínú aṣálẹ̀ Ṣúrì. Wọ́n lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù náà, wọn kò sì rí omi.
23. Nígbà tí wọ́n dé Márà, wọn kò lè mu omi Márà nítorí omi náà korò (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Márà: ibi ìkorò).
24. Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mósè wí pé, “Kí ni àwa yóò mu?”
25. Mósè sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn.Níbẹ̀ ni Olúwa ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò.
26. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí òfin Olúwa Ọlọ́run, ti ìwọ si ṣe ohun tí ó tọ́ ni ojú rẹ̀, ti ìwọ sì tẹ̀lé ohun tí ó pàṣẹ, ti ìwọ si pa ìlànà rẹ̀ mọ́. Èmi kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn àrùn wọ̀n-ọn-nì ti mo mú wá sórí àwọn ará Éjíbítì wá sí ara rẹ, nítorí èmi ni Olúwa ti ó mú ọ lára da.”
27. Nígbà ti wọ́n dé Élímù, nibi ti kànga omi méjìlá (12) àti àádọ́rin (70) ọ̀pẹ gbé wà, wọ́n pàgọ́ ṣíbẹ̀ ni etí omi.