5. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba Éjíbítì pé àwọn ènìyàn náà ti sá lọ, ọkàn Fáráò àti àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ yí padà sí àwọn ènìyàn, wọ́n sì wí pé, “Kí ni ohun tí àwa ṣe yìí? Àwa ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ó lọ, a sì ti pàdánù ìsìnrú wọn.”
6. Ó sì di kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀,
7. ó mú ẹgbẹ̀ta (600) ọmọ ogun oníkẹ̀kẹ́ tí ó jáfáfá jùlọ àti gbogbo ọmọ ogun oníkẹ̀kẹ́ mìíràn ní Éjíbítì, olórí sì wà fún olúkúlùkù wọn.
8. Olúwa ṣe ọkàn Fáráò ọba Éjíbítì le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń jáde lọ ní àìbẹ̀rù.
9. Àwọn ará Éjíbítì ń lépa wọn pẹ̀lú gbogbo ẹsin kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀, wọ́n sì lé wọn bá ni ibi tí wọ́n pa àgọ́ sí lẹ́bá òkun ní ìhà Pi-Hahírótù, ni òdì kejì Baali-Ṣéfónì.
10. Bí Fáráò ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Éjíbítì tó súnmọ́ wọn. Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Ísírẹ́lì, wọ́n kígbe sókè sí Olúwa.
11. Wọ́n sọ fún Móse pé, “Ṣe nítorí pé kò sí ibojì ni Éjíbítì ní ìwọ se mú wa wá láti kú sínú ihà? Kí ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa ti ìwọ fi mú wa jáde láti Éjíbítì wá?