1. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú u yín dé ilẹ̀ náà, tí ẹ ó wọ̀ lọ láti gbà, tí ó sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè kúrò níwájú u yín: Àwọn ará Hítì, Gígásì, Ámórì, Kénánì, Pérésì, Hífì àti àwọn ará Jébúsì: Àwọn orílẹ̀ èdè méje tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì pọ̀ jù yín lọ,
2. nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá sì ti fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́, tí ẹ sì ti ṣẹ́gun wọn, kí ẹ pa wọ́n run pátapáta. Ẹ má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà, ẹ kò sì gbọdọ̀ sàánú un wọn.
3. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ bá wọn dá àna. Àwọn ọmọbìnrin yín kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọkùnrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín,
4. torí pé wọ́n á yí àwọn ọmọ yín padà kúrò lẹ́yìn mi, láti jẹ́ kí wọn máa sin òrìṣà, ìbínú Olúwa yóò sì wá sórí yín, yóò sì run yín kíákíá.
5. Èyí ni kí ẹ ṣe sí wọn: Ẹ wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ bi òpó òkúta ibi mímọ́ òrìṣà wọn lulẹ̀, òpó òrìṣà Áṣérà wọn ni kí ẹ gé lulẹ̀ kí ẹ sì sun ère òrìṣà wọn ní iná.
6. Torí pé ènìyàn mímọ́ ni ẹ jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run yín, Olúwa Ọlọ́run yín ti yàn yín láàrin gbogbo ènìyàn lórílẹ̀ ayé, láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀: ohun ìní iyebíye rẹ̀.
7. Olúwa kò torí pé ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ju àwọn ènìyàn yóòkù lọ yàn yín, ẹ̀yin sáà lẹ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn.