nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá sì ti fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́, tí ẹ sì ti ṣẹ́gun wọn, kí ẹ pa wọ́n run pátapáta. Ẹ má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà, ẹ kò sì gbọdọ̀ sàánú un wọn.