1. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú u yín dé ilẹ̀ náà, tí ẹ ó wọ̀ lọ láti gbà, tí ó sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè kúrò níwájú u yín: Àwọn ará Hítì, Gígásì, Ámórì, Kénánì, Pérésì, Hífì àti àwọn ará Jébúsì: Àwọn orílẹ̀ èdè méje tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì pọ̀ jù yín lọ,
2. nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá sì ti fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́, tí ẹ sì ti ṣẹ́gun wọn, kí ẹ pa wọ́n run pátapáta. Ẹ má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà, ẹ kò sì gbọdọ̀ sàánú un wọn.
3. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ bá wọn dá àna. Àwọn ọmọbìnrin yín kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọkùnrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín,
4. torí pé wọ́n á yí àwọn ọmọ yín padà kúrò lẹ́yìn mi, láti jẹ́ kí wọn máa sin òrìṣà, ìbínú Olúwa yóò sì wá sórí yín, yóò sì run yín kíákíá.
5. Èyí ni kí ẹ ṣe sí wọn: Ẹ wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ bi òpó òkúta ibi mímọ́ òrìṣà wọn lulẹ̀, òpó òrìṣà Áṣérà wọn ni kí ẹ gé lulẹ̀ kí ẹ sì sun ère òrìṣà wọn ní iná.
6. Torí pé ènìyàn mímọ́ ni ẹ jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run yín, Olúwa Ọlọ́run yín ti yàn yín láàrin gbogbo ènìyàn lórílẹ̀ ayé, láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀: ohun ìní iyebíye rẹ̀.
7. Olúwa kò torí pé ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ju àwọn ènìyàn yóòkù lọ yàn yín, ẹ̀yin sáà lẹ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn.
8. Ṣùgbọ́n torí Ọlọ́run fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó se fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Fáráò ọba Éjíbítì.
9. Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé Olúwa Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olótìítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
10. Ṣùgbọ́nàwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ni yóò san ẹ̀san fún ní gbangba nípa pípa wọ́n run;kì yóò sì jáfara láti san ẹ̀san fún àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ní gbangba.
11. Nítorí náà ẹ kíyési láti máa tẹ̀lé àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí mo fun un yín lónìí.
12. Bí ẹ bá ń kíyèsí àwọn òfin wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣọ́ra láti ṣe wọ́n, nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run yín yóò pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún un yín, bí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín.
13. Yóò fẹ́ràn yín, yóò bùkún un yín yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i. Yóò bùkún èṣo inú un yín, ọ̀gbìn ilẹ̀ yín, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun àti òróró yín, àwọn màlúù, agbo ẹran yín, àti àwọn àgùntàn, ọ̀wọ́ ẹran yín, ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá yín láti fún un yín.