2 Sámúẹ́lì 23:18-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ábíṣáì, arákùnrin Jóábù, ọmọ Sérúíà, òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta. Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.

19. Ọlọ́lá jùlọ ni òun jẹ́ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: ó sì jẹ́ olórí fún wọn: ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ìṣáájú.

20. Bénáyà, ọmọ Jéhóíádà, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabiseélì, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Áríélì méjì ti Móábù; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjòdídì.

21. Ó sì pa ará Éjíbítì kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò: ará Éjíbítì náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n òun sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Éjíbítì náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á.

22. Nǹkan wọ̀nyí ní Banáyà ọmọ Jéhóíádà ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà.

23. Nínú àwọn ọgbọ̀n náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dáfídì sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀.

24. Ásáhélì arákùnrin Jóábù sì Jásí ọ̀kan nínú àwọn ọgbọ̀n náà;Élíhánánì ọmọ Dódò ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù;

25. Ṣámà ará Háródì,Élíkà ará Háródì.

26. Hélésì ará Pálitì,Irá ọmọ Íkéṣì ará Tékóà;

27. Ábíésérì ará Ánétótì,Móbúnnáì Húṣátítì;

28. Sálímónì ará Áhóhì,Máháráì ará Nétófà;

29. Hélébù ọmọ Báánà, árá Nétófà,Íttaì ọmọ Ríbáì to Gíbéà ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì;

30. Bénáyà ará Pírátónì,Hídáyì tí àfonífojì.

31. Ábíálíbónì ará Áríbà,Ásámífétì Báríhúmítì;

32. Élíáhíbà ará Sáálíbónì,Jáṣénì Gísónítì,Jónátanì;

33. Ṣámà ará Hárárì,Áhíámù ọmọ Ṣárárì ará Hárárì;

34. Élífélétì ọmọ Áhásibáyì, ọmọ ará Máákíhà,Élíámù ọmọ Áhítófélì ará Gílónì;

2 Sámúẹ́lì 23