2 Sámúẹ́lì 15:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa wa ọba ń fẹ́, wò ó, àwa ìránṣẹ rẹ̀ ti murá.”

16. Ọba sì jáde, gbogbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ọba sì fì mẹ́wàá nínú àwọn obìnrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa sọ́ ilé.

17. Ọba sì jáde, gbogbo ènìyàn sì tẹ̀lé e, wọ́n sì dúró ní ibìkan tí ó jìnnà.

18. Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì kọjá sí ìwájú rẹ̀, àti gbogbo àwọn Kérétì, àti gbogbo àwọn Pélétì, àti gbogbo àwọn ará Gítì, ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Gátì wá, sì kọjá níwájú ọba.

2 Sámúẹ́lì 15