14. Dáfídì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ kò fi bẹ̀rù láti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti fi pa ẹni àmì òróró Olúwa?”
15. Nígbà náà Dáfídì pe ọ̀kan nínú ọkùnrin, ó sì wí pé, “Lọ, gbé e lulẹ̀!” Nígbà náà ó gbé e lulẹ̀, ó sì kú.
16. Nítorí Dáfídì wí fún un pé, “Ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò wà lórí ara rẹ, nítorí ẹnu ara rẹ ni o fi sọ pé ‘Mo pa ẹni àmì òróró Olúwa.’ ”
17. Dáfídì sì fi orin arò yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Ṣọ́ọ̀lù àti lórí Jónátanì ọmọ rẹ̀,
18. Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Júdà ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun (a kọ ọ́ sí inú ìwé Jáṣárì):
19. “Ogo rẹ, Ísírẹ́lì ni a pa ní òkè gíga rẹ.Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú!
20. “Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gátì,ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Áṣíkélónì,kí àwọn ọmọbìnrin Fílístínì má bá à yọ̀,kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má baà dunnú.
21. “Ẹ̀yin òkè Gílíbóà,kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò,tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá.Nítorí ibẹ̀ ni aṣà alágbára ti ṣègbé,aṣà Ṣọ́ọ̀lù, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án.
22. Ọrun Jónátánì kì í padàbẹ́ẹ̀ ni idà Ṣọ́ọ̀lù kì í padà lásán,láì kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa,àti ẹran àwọn alágbára.