1. Ní ọdún kẹta Hóséà ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì, Heṣekíàyà ọmọ Áhásì ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ ìjọba.
2. Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó ti di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ A bì ọmọbìnrin Ṣakaríàyà.
3. Ó sì ṣe ohun tí ó dára níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí i baba rẹ̀ Dáfídì ti ṣe.
4. Ó mú ibi gíga náà kúrò, ó sì fọ́ òkúta àwọn ère ó sì gé àwọn ère lulẹ̀ ó sì fọ́ ejò idẹ náà túútúú tí Móṣè ti ṣe, títí di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sun tùràrí sí. (Wọ́n sì pè é ní Néhúṣítanì.)
5. Heṣekáyà sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Kò sì sí ẹnìkan tí ó dàbí tirẹ̀ lára gbogbo àwọn ọba Júdà, bóyá kí ó tó jẹ tàbí lẹ́yìn rẹ̀.
6. Ó sún mọ́ Olúwa, kò sì dẹ́kun láti tì í lẹ́yìn: ó sì pa òfin Olúwa mọ́ tí ó ti fi fún Mósè.
7. Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀; ó sì ń ṣe rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. Ó ṣe ọ̀tẹ̀ sí ọba Ásíríà kò sì sìn-ín.
8. Láti ilé-ìṣọ́ títí dé ìlú olódi, ó sì pa àwọn ará Fílístínì run, àti títí dé Gásà àti agbègbè rẹ̀.
9. Ní ọdún kẹrin ọba Heṣekáyà, nígbà tí ó jẹ́ ọdún keje Hóséà ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì. Ṣálímánésérì ọba Áṣíríà yàn lára Ṣamáríà ó sì tẹ̀dó tì í.
10. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta Ásíríà gbé e. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó Ṣamáríà ní ọdún kẹfà Heṣekáyà tí ó sì jẹ́ ọdún kẹsàn-án Hóṣéà ọba Ísírẹ́lì.
11. Ọba Áṣíríà lé Ísírẹ́lì kúrò ní Áṣíríà, wọ́n sì ṣe àtìpó wọn ní Hálà, ní Gósánì létí odò Hábórì àti ní ìlú àwọn ará Médíà.