2 Kíróníkà 9:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ayaba Ṣébà gbọ́ nípa òkìkí Sólómónì, ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù láti dán-an-wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le. Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasíẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Sólómónì ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀.

2. Sólómónì sì dáa lóhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyíkéyìí tí kò lè ṣe àlàyé fún.

3. Nígbà tí ayaba Ṣébà rí ọgbọ́n Sólómónì àti pẹ̀lu ilé tí ó ti kọ́,

4. Oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì rẹ̀, àti ìjòkòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti dídúró àwọn ìránṣẹ́ nínú aṣọ wọn, àti àwọn agbọ́tí nínú aṣọ wọn àti ẹbọ ọrẹ sísun tí ó ṣe ní ilé Olúwa, ó sì ní ìdálágara.

5. Ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ, òtítọ́ ni.

6. Ṣùgbọ́n èmi kò gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́ àyàfi ìgbà tí mó dé ibí tí mo sì ri pẹ̀lú ojú mi. Nítòótọ́, kì í tilẹ̀ ṣe ìdàjọ́ ìdajì títóbi ọgbọ́n rẹ ní a sọ fún mi: ìwọ ti tàn kọ já òkìkí tí mo gbọ́.

7. Báwo ni inú àwọn ọkùnrin rẹ ìbá ṣe dùn tó! Báwó nínú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí n dúró nígbà gbogbo níwájú rẹ láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ!

2 Kíróníkà 9