1. Nítorí ìdí èyí, nígbà tí ara mi kò gbà á mọ́, mo pinnu láti nìkan dúró ní ìlú Átẹ́nì.
2. Mo sì rán Tímótíù, arákùnrin àti alábáṣiṣẹ́ pọ̀ wá, láti bẹ̀ yín wò. Mo rán an láti fún ìgbàgbọ́ yín lágbára àti láti mú yín lọ́kà le; àti kí ó má sì ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, nínú ìṣòro tí ẹ ń là kọjá.
3. Láìsí àníàní, ẹ mọ̀ gbangba pé, irú ìṣòro báwọ̀nyí wà nínú ètò Ọlọ́run fún àwa Kírísítẹ́nì.
4. Tó bẹ́ẹ̀ tí a fi kìlọ̀ fún yín pé ìjìyà inúnibíni yóò de. Ó sì rí bẹ́ẹ̀ nítòótọ́.
5. Bí mo wí tẹ́lẹ̀, nígbà tí ara mi kò gba ìdákẹ́jẹ́ẹ́ náà, mo rán Tímótíù láti bẹ̀ yín wò, kí ó lè mọ̀ bóyá ìgbàgbọ́ yín sì dúró gbọn-ingbọn-in. Mo funra sí i wí pé, sàtánì ti ṣẹ́gun yín. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ wa (láàrin yín) jásí aṣán.
6. Nísìnsinyìí, Tímótíù ti dé pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀ wí pé, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín sì lágbára bí i ti àtẹ̀yìnwá. Inú wa dùn láti gbọ́ wí pé ẹ sì ń rántí ìbágbé wa láàrin yín pẹ̀lú ayọ̀. Tímótíù tún fi yé wa pé bí ó ti mú wa lọ́kàn tó láti rí i yín, ni ó ṣe ẹ̀yin pàápàá.
7. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, inú wá dùn jọjọ nínú gbogbo ìyọnu àti ìjìyà wa níbí nítorí pé àwa mọ̀ nísinsinyìí pé, ẹ̀yin sì dúró gbọn-ingbọn-in fún Olúwa.