13. Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìráńṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀.
14. Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí Kẹ́tìlì tàbí òdù, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣílò.
15. Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìráńṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, “Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfàá; nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò se tútù.”
16. Bí ọkùnrin náà bá sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí wọn ó sun ọ̀rá náà nísinsin yìí, kí o sì mú iyekíye tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́;” nígbà náà ni yóò dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi í fún mi nísinsin yìí, bí kó ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó fi agbára gbà á.”
17. Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùrin náà sì tóbi gidigidi níwájú Olúwa: nítorí tí ènìyàn kórìíra ẹbọ Olúwa.
18. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì ń ṣe ìráńṣẹ́ níwájú Olúwa, ọmọdé, ti a wọ̀ ní éfódì ọ̀gbọ̀.
19. Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ ìlekè péńpé fún un, a sì máa mu wá fún un lọdọọdún, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ gòkè wá láti ṣe ìrúbọ ọdún.
20. Élì súre fún Elikánà àti aya rẹ̀ pé, “Kí Olúwa fún ọ ní irú-ọmọ láti ara obìnrin yìí wá, nítorí ẹ̀bùn tí ó béèrè tí ó sì tún fún Olúwa.” Wọ́n sì lọ sí ilé wọn.
21. Olúwa si bojú wo Hánà, ó sì lóyún, ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì. Sámúẹ́lì ọmọ náà sì ń dàgbà níwájú Olúwa.
22. Élì sì di arúgbó gidigidi, ó sì gbọ́ gbogbo èyí ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sí gbogbo Ísírẹ́lì; àti bi wọ́n ti máa ń bá àwọn obìnrin sùn, tí wọ́n máa ń péjọ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ.
23. Ó sì wí fún wọn pé, kí ni ó ti ri “Èétirí tí èmi fi ń gbọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí yín? Nítorí tí èmi ń gbọ́ iṣẹ́ búburú yín láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.