1 Sámúẹ́lì 10:20-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Nígbà Sámúẹ́lì mú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.

21. Ó kó ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣíwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Mátírì. Ní ìparí a sì yan Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i,

22. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Olúwa pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?” Olúwa sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrin àwọn ẹrù.”

23. Wọ́n sáré, wọ́n sì mú un jáde wá. Bí ó ti dúró láàárin àwọn ènìyàn, ó sì ga ju gbogbo àwọn tí ó kù lọ láti èjìká rẹ̀ sókè.

24. Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí Olúwa ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàárin gbogbo àwọn ènìyàn.”Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!”

25. Sámúẹ́lì ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn àwọn ìlànà ìjọba. Ó kọ wọ́n sínú ìwé, ó sì fi lélẹ̀ níwájú Olúwa. Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì tú àwọn ènìyàn ká olúkúlùkù sí ilé e rẹ̀.

1 Sámúẹ́lì 10