1 Ọba 15:5-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nítorí tí Dáfídì ṣe èyí tí ó dára ní ojú Olúwa, tí kò sì kùnà láti pa gbogbo èyí tí Olúwa pa láṣẹ fún un mọ́ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo; bí kò ṣe ní kìkì ọ̀ràn Ùráyà ará Hítì.

6. Ogun sì wà láàrin Réhóbóámù àti Jéróbóámù ní gbogbo ọjọ́ ayé Ábíjà.

7. Níti ìyókù ìṣe Ábíjà, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, a kò há kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà? Ogun sì wà láàrin Ábíjà àti Jéróbóámù.

8. Ábíjà sì sùn pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dáfídì. Áṣà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

9. Ní ogún ọdún Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Áṣà jọba lórí Júdà,

10. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù ní ọdún mọ́kànlélógójì. Orúkọ ìyá ìyá rẹ̀ sì ni Máákà, ọmọbìnrin Ábúsálómù.

11. Áṣà sì ṣe èyí tí ó dára lójú Olúwa, bí Dáfídì baba rẹ̀ ti ṣe.

12. Ó sì mú àwọn tí ń ṣe panṣágà kúrò ní ilẹ̀ náà, ó sì kó gbogbo ère tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe kúrò.

13. Ó sì mú Máákà ìyá ìyá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún òrìṣà rẹ̀. Áṣà sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì dáná sun ún níbi odò Kídírónì.

14. Ṣùgbọ́n kò mú àwọn ibi gíga kúrò, síbẹ̀ ọkàn Áṣà pé pẹ̀lú Olúwa ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo.

15. Ó sì mú wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò tí òun àti bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wọ ilé Olúwa

1 Ọba 15