1 Kíróníkà 29:24-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn ọkùnrin alágbára, pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọba Dáfídì tẹrí ara wọn ba fún ọba Sólómónì.

25. Olúwa gbé Solómónì ga púpọ̀ ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì kẹ́ ẹ ní ìkẹ́ ọlá ńlá, ní irú èyí tí a kò kẹ́ ọba kankan ṣáájú Rẹ̀ tí ó jẹ lórí Ísírẹ́lì.

26. Dáfídì ọmọ Jéṣè jẹ́ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.

27. Ó jọba lórí Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún; ọdún méje ni ó jọba ní Hẹ́súrónì, ó sì jọba ní ọdún mẹ́talélọ́gbọ̀n (33) ní Jérúsálẹ́mù.

28. Òun sì darúgbó, ó sì kú ikú rere, ó gbádùn ẹ̀mí gígùn, ọlá àti ọrọ̀. Sólómónì ọmọ Rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀

29. Ní ti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba ọba Dáfídì, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, a kọ wọ́n sínú ìwe ìrántí ti Sámúẹ́lì aríran, ìwé ìrántí ti Nátanì wòlíì àti ìwé ìrántí ti Gádì aríran,

30. lápapọ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti agbára Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìgbà tí ó kọjá lórí Rẹ̀, àti lórí Ísírẹ́lì, àti lórí gbogbo àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ náà.

1 Kíróníkà 29