1. Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti fi ìdí kalẹ̀ sínú ààfin Rẹ̀, ó sọ fún Nátanì wòlíì pé, Èmi nìyí, tí ń gbé inú òpèpè (igi) ààfin kédárì nígbà tí àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú Olúwa wà lábẹ́ àgọ́
2. Nátanì dá Dáfídì lóhùn pé, Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.
3. Ní àsálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Nátanì wá, wí pé:
4. “Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dáfídì, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé.
5. Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Isírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé.