Sáàmù 91:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò nì ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀

14. “Nítorí tí ìfẹ́ Rẹ sì mi,”“èmi yóò gbà ọ́;èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.

15. Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dáa lóhùn;èmi yóò wà pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ipọ́nju,èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un

16. Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùnèmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”

Sáàmù 91