1. Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìrán dé ìran.
2. Kí a to bí àwọn òkè nlaàti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.
3. Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,wí pé “padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn”.
4. Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú Rẹ,bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
5. Ìwọ gbá ènìyàn dánù nínú oorun ikú;wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
6. Lótìítọ́ ní òwúrọ́ ó yọ tuntunní àsálẹ́ ní yóò gbẹ tí yóò sì Rẹ̀ dànù.
7. A pa wá run nípa ìbínú Rẹnípa ìbínú Rẹ ara kò rọ̀ wá.
8. Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú Rẹ,àti ohun ìkọ̀kọ̀ wà nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú Rẹ,