Sáàmù 9:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,àti gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.

18. Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a ò ní gbàgbé láéláé,ìrètí àwọn ti ó talakà lójú kí yóò ṣègbé láéláé.

19. Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀ èdè ni iwájú Rẹ.

20. Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa;jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela

Sáàmù 9