Sáàmù 73:21-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nígbà tí inú mi bàjẹ́àti ọkàn mi sì korò,

22. Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye;mo jẹ́ ẹranko ní ìwájú Rẹ.

23. Ṣíbẹ̀ mo wà pẹ̀lú Rẹ nígbà gbogbo;ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

24. Ìwọ fi ìmọ̀ràn Rẹ tọ́ miní kẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo

25. Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ?Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn Rẹ.

26. Ara mi àti ọkàn mi leè kùnàṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí miàti ìpín mi títí láé.

27. Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbéìwọ ti pa gbogbo wọn run;tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ Rẹ

28. Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́runÈmi ti fi Olúwa Ọlọ́run ṣe ààbò mi;Kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ Rẹ.

Sáàmù 73