Sáàmù 73:14-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu;a sì ń jẹ mí níyà ní gbogbo òwúrọ̀.

15. Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,”Èmi ó ṣẹ̀sí ìran àwọn ọmọ Rẹ̀.

16. Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí,O jẹ́ ìnilára fún mi.

17. Tí tí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run;Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi,

18. Lótítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.

19. Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìíbí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọn pátapáta!

20. Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí,bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa,ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.

21. Nígbà tí inú mi bàjẹ́àti ọkàn mi sì korò,

22. Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye;mo jẹ́ ẹranko ní ìwájú Rẹ.

23. Ṣíbẹ̀ mo wà pẹ̀lú Rẹ nígbà gbogbo;ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

24. Ìwọ fi ìmọ̀ràn Rẹ tọ́ miní kẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo

25. Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ?Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn Rẹ.

26. Ara mi àti ọkàn mi leè kùnàṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí miàti ìpín mi títí láé.

27. Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbéìwọ ti pa gbogbo wọn run;tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ Rẹ

Sáàmù 73