Sáàmù 73:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítòótọ̀ Ọlọ́run dára fún Ísírẹ́lì,fún àwọn ọlọ́kàn funfun.

2. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán;ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.

3. Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣeféfénígbà tí mo bá rí ọlá àwọn ènìyàn búburú.

4. Wọn kò ṣe wàhálà;ara wọn mókun wọn sì lágbára.

5. Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ si ènìyàn;a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlomíràn.

Sáàmù 73