6. Dìde, Olúwa, nínú ìbínú Rẹ;dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀ta mi.Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo.
7. Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yí ká.Jọba lórí wọn láti òkè wá;
8. Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ.
9. Ọlọ́run Olódodo,Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn,tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburútí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́.
10. Aṣà mi ní Ọlọ́run tí ó gajù,ẹni tí ń dáàbò bo àwọn ẹni gíga nípa ti èmi.