Sáàmù 7:11-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ọlọ́run ni onídàájọ́ tòótọ́,Ọlọ́run tí ń sọ ìrúnú Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.

12. Bí kò bá yípadà,òun yóò pọ́n idà Rẹ̀ múó ti fa ọrun Rẹ̀ le náó ti múra Rẹ̀ sílẹ̀

13. Ó ti pèṣè ohun ìjà ikú sílẹ̀;ó ti pèṣè ọfà iná sílẹ̀.

14. Ẹni tí ó lóyún ohun búburú,tí ó sì lóyùn wàhálà ó bí èké jáde.

15. Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jádejìn sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀.

16. Wàhálà tí ó fà padà sórí Rẹ̀;Ìwà ipá Rẹ̀ padà sórí ara Rẹ̀.

17. Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo Rẹ̀Èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa tí ó ga jùlọ.

Sáàmù 7