1. Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú Rẹ;gba mí là kí o sì tú mí sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi,
2. kí wọn ó má bá à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìúnwọn a ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gba mí.
3. Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyítí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi
4. Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mití mo ja ọ̀ta mí lólè láìnídìí:
5. Nígbà náà jẹ́ kí ọ̀ta mi le mi kí wọn sì mú mi;jẹ́ kí òun kí ó tẹ ẹ̀mí mi mọ́lẹ̀kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela