Sáàmù 62:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ní tòótọ́, asán ní àwọn ọmọ ènìyàn, èkési ni àwọn olóyè, wọn gòkè nínú ìwọ̀nbákan náà ni wọn fẹ́rẹ̀ jù asán lọlápapọ̀ wọn jẹ èémí.

10. Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnílára,tàbí gbéraga nínú olè jíjà,nítòótọ́ bí ọrọ̀ Rẹ̀ ń pọ̀ síi,má ṣe gbẹ́kẹ̀ Rẹ̀ lé wọn.

11. Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mogbọ́ èyí pé, ti Ọlọ́run ní agbára

12. Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tirẹ ni àánúnitorí ti iwọ san án fun olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ Rẹ̀.

Sáàmù 62