Sáàmù 56:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bàmí,èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4. Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ Rẹnínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà míkí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?

5. Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.

6. Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n baWọn ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ miwọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.

7. Wọ́n ha le mú un jẹ gbé?Ní ìbínú Rẹ, Ọlọ́run, wó àwọn ènìyàn yìí lulẹ̀ Ọlọ́run!

8. Kọ ẹkún mi sílẹ̀;kó omije mi sí ìgò Rẹwọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ Rẹ bí?

Sáàmù 56