10. Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmíàti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.
11. Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńláàti gbogbo ẹ̀dá alààyé tí ó wà ní orí ilẹ ni tèmi
12. Bí ebi tílẹ̀ ń pá mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbotí ó wa ní inú Rẹ̀.
13. Ǹjẹ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbímú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́?
14. Rú ẹbọ ọrẹ sí Ọlọ́runsan ẹ̀jẹ̀ Rẹ fún ọ̀gá ògo,
15. Kí o sì pe mí ni ọjọ́ ìpọ́njú,èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.
16. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọnènìyàn búburú:“Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọtàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mu mi ní ẹnu Rẹ?
17. Ìwọ kórìíra àsẹ miìwọ sì sá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan
18. Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́-ọnìwọ sì da ara Rẹ̀ dé àwọn alágbèrè
19. Ìwọ lo ẹnu Rẹ̀ fún aburúìwọ sì ń fi ahọ́n Rẹ pète ẹ̀tàn
20. Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí ará-kun-rin Rẹ,ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá Rẹ jẹ́