12. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́o sì dàbí ẹranko tí o sègbé
13. Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ogbàgbọ́ nínú ara wọn,àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn,tí o gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela
14. Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkúikú yóò jẹun lórí wọn;ẹni tí ó dúró ṣinṣin ní yóòjọba lórí wọn ní òwúrọ̀;Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.
15. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padàkúrò nínú isà òkúyóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara Rẹ̀.
16. Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnikan bá di ọlọ́rọ̀Nígbà tí ìyìn ilé Rẹ̀ ń pọ̀ síi
17. nítorí kì yóò mú òun kan dání nígbà tí ó bá kú,ògo Rẹ̀ kòní báa sọ̀kálẹ̀ sí ipò òkú
18. Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara Rẹ̀.Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere
19. Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba Rẹàwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.
20. Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.