Sáàmù 48:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Jẹ́ kí òkè Síónì kí ó yọ̀kí inú àwọn ọmọbìnrin Júdà kí ó dùnnítorí ìdájọ́ Rẹ̀.

12. Rìn Síónì kiri lọ yíká Rẹ̀,ka ilé ìsọ́ Rẹ̀

13. Kíyèsí odi Rẹ̀kíyèsí àwọn ààfin Rẹ̀kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀

14. Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayéÒun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

Sáàmù 48