Sáàmù 46:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Tí omi Rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mìtí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára Rẹ̀. Sela

4. Odò ńlá kan wà tí sísàn Rẹ̀ mú ìnú ìlú Ọlọ́run dùnibi mímọ́, nibi ti ọ̀gá ògo ń gbé.

5. Ọlọ́run wà pẹ̀lú Rẹ̀, kò ní yẹ̀:Ọlọ́run yóò ràn an lọ́wọ́ ní kùtùkùtù ọ̀wúrọ̀

6. Àwọn orílẹ̀ èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba subúó gbé ohun Rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.

7. Ọlọ́run awọn ọmọ ogún wà pẹ̀lú waỌlọ́run Jákọ́bù ni ààbò wa

8. Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwairú ahoro tí ó ṣe ní ayé

9. O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayéó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjìó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná

Sáàmù 46