1. Ọlọ́run ni ààbò àti agbára waó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ nínú ìgbà ìpọ́njú.
2. Nítori náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ sí ayé ní ìdítí òkè sì ṣubú sínú òkun
3. Tí omi Rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mìtí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára Rẹ̀. Sela
4. Odò ńlá kan wà tí sísàn Rẹ̀ mú ìnú ìlú Ọlọ́run dùnibi mímọ́, nibi ti ọ̀gá ògo ń gbé.
5. Ọlọ́run wà pẹ̀lú Rẹ̀, kò ní yẹ̀:Ọlọ́run yóò ràn an lọ́wọ́ ní kùtùkùtù ọ̀wúrọ̀
6. Àwọn orílẹ̀ èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba subúó gbé ohun Rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.