Sáàmù 39:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo wí pé,èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mikí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnuníwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburúbá ń bẹ ní iwájú mi.

2. Mo fi ìdákẹ́ ya odi;mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ síi.

3. Àyà mi gbóná ní inú mi,nígbà tí mo ń ṣàṣàrò,ina ràn;nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀.

4. Olúwa,jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti ríkí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.

5. Ìwọ ti ṣe ayé mibí ìbú àtẹ́lẹwọ́,ọjọ́ orí mi sì dàbí asánní iwájú Rẹ:Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínúìjókòó rere Rẹ̀ jásí asán pátapáta. Sela

6. Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.

7. Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, Olúwa,kín ni mo ń dúró dè?Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Rẹ.

8. Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gànàwọn ènìyàn búburú.

9. Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;èmi kò sì ya ẹnu mi,nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.

10. Mú ìnà Rẹ̀ kúrò ní ara mi;èmí ṣègbé tán nípa ìlù ọwọ́ Rẹ.

11. Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,ìwọ a mú ẹwà Rẹ parunbí kòkòrò aṣọ;nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.

Sáàmù 39