Sáàmù 29:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ Rẹ̀;sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

3. Ohùn Olúwa ré àwọn omi kọjá;Ọlọ́run ògo sán àrá, Olúwa náà, alágbára ń bẹ lóríi omi púpọ̀.

4. Ohùn Olúwa ní agbára;ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.

5. Ohùn Olúwa fọ́ igi kédárì; Olúwa náà ló fọ́ igi kédárì Lébánónì.

6. Ó mú Lébánónì fo bí i ọmọ màlúù,àti Síríónì bí ọmọ àgbáǹréré.

7. Ohùn Olúwa ń yabí ọwọ́ iná mọ̀nà

Sáàmù 29