Sáàmù 24:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí Rẹ̀,tí ń ṣe àfẹ́rí Rẹ̀, Ọlọ́run Jákọ́bù. Sela

7. Ẹ gbé orí yín sókè, Áà! Ẹ̀yin ọ̀nà;Kí á sì gbe yín sókè, áà! Ẹyin ilẹ̀kùn ayérayé!Kí ọba ògo le è wọlé.

8. Ta ni ọba ògo náà? Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le, Olúwa gan-an, tí o lágbára ní ogun.

9. Gbé orí yín sókè, áà! Ẹ̀yin ọ̀nà;Kí a sì gbé yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,Kí ọba ògo le è wọlé wá.

10. Ta ni ọba ogo náà? Olúwa àwọn ọmọ ogunÒun ni ọba ògo náà. Sela

Sáàmù 24