Sáàmù 22:19-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi;Áà Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wa fún àtìlẹ́yìn mi!

20. Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.

21. Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ kìnnìún;Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.

22. Èmi yóò kéde orúkọ ọ̀ Rẹ láàrin arákùnrin àti arábìnrin mi;nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.

23. Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹyìn-ín!Gbogbo ẹ̀yin ìran Jákọ́bù, ẹ fi ògo fún-un!ẹ dìde fún-un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú ọmọ Ísírẹ́lì!

24. Nítorí pé òun kò ṣááta, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíraìpọ́njú àwọn tí a ni lára;kò sì fi ojú Rẹ̀ pamọ́ fún miṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.

25. Lati ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ẹsẹ̀ ìyìn mi nínú àwùjọ ńlá yóò ti wá;ẹ̀jẹ́ Rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù Rẹ̀

26. talákà yóò jẹ yóò sì yó;àwọn tí n wá Olúwa yóò yinjẹ́ kí ẹ̀mí Rẹ̀ wà láàyè títí ayárayé!

Sáàmù 22