Sáàmù 18:42-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́;mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.

43. Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn;Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ́ èdè;àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí.

44. Wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n gbọ́ gbàmí;àwọn ọmọ àjèjì yóò fi ẹ̀tàn tẹríba fún mi.

45. Àyà yóò pá àlejò;wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.

46. Olúwa wà láàyè! Olùbùkún ni àpáta mi!Gbígbé ga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.

47. Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi,tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà ní abẹ́ mi,

48. tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí.Ìwọ gbé mi ga ju àwọn tí ó dìde sí mi lọ;lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí.

49. Títí láéláé èmi yóò máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, ìwọ Olúwa;Èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ Rẹ.

50. Ó fún Ọba Rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá;ó fi ìkáànú àìṣẹ̀tàn fún ẹni-àmì-òróró Rẹ̀,fún Dáfídì àti ìran Rẹ̀ títí láé.

Sáàmù 18