Sáàmù 18:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ìrora ikú yí mi kà,àti ìsàn omi àwọn ènìyàn búbúrú dẹ́rùbà mí.

5. Okùn isà òkú yí mi ká,ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.

6. Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa;Mo sunkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́.Láti inú tẹ́ḿpìlì Rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;ẹkún mi wá sí iwájú Rẹ̀, sí inú etí Rẹ̀.

7. Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì pẹ̀lú,ìpìlẹ̀, àwọn òkè gíga sì sídìí;wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.

8. Èéfín ti ihò imú Rẹ̀ jáde wá;Iná ajónirun ti ẹnu Rẹ̀ jáde wá,ẹ̀yin iná bú jáde láti inú Rẹ̀.

9. Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá;àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ Rẹ̀.

Sáàmù 18