1. Ẹ fi ìyìn fún OlúwaẸ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wáẸ fi ìyìn fún un níbi gíga
2. Ẹ fi ìyìn fún un,gbogbo ẹ̀yin ángẹ́lì Rẹ̀Ẹ fi ìyìn fún un,gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun Rẹ̀
3. Ẹ fi ìyìn fún un,oòrùn àti òṣùpáẸ fi ìyìn fún un,gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
4. Ẹ fi ìyìn fún un,ẹ̀yin ọ̀run àwọn ọ̀run gígaàti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run
5. Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwanítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
6. Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláéó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.
7. Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wáẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbiàti ẹ̀yin ibú òkun