Sáàmù 132:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa, rántí Dáfídìnínú gbogbo ìpọ́njú Rẹ̀:

2. Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa,tí ó sì ṣe ìlèrí fún Alágbára Jákọ́bù pé.

3. Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ,bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gùn orí àkéte mi:

4. Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,

5. Títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa,ibùjókòó fún Alágbára Jákọ́bù.

6. Kíyèsí i, àwa gbúroo Rẹ̀ ni Éfúrátà:àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.

7. Àwa ó lọ sínú àgọ́ Rẹ̀:àwa ó máa sìn níbi àpótí-ìtìsẹ̀ Rẹ̀

8. Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi Rẹ:ìwọ, àti àpótí agbára Rẹ.

9. Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà Rẹ:kí àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.

10. Nítorí tí Dáfídì ìránṣẹ́ Rẹ̀Má ṣe yí ojú ẹni-òróró Rẹ padà.

11. Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dáfídì:Òun kí yóò yípadà kúrò nínú Rẹ̀,nínú irú ọmọ inú Rẹ ní èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ Rẹ.

12. Bí àwọn ọmọ Rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókoo lórí ìtẹ́ Rẹ láéláé.

Sáàmù 132