1. Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójúláti ìgbà èwe mi wá ni kíÍsírẹ́lì kí ó wí nísinsinyí
2. Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójúláti ìgbà èwe mi wá;ṣíbẹ̀ wọn kò tíì borí mi.
3. Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:wọ́n sì là aporo wọn gígùn.
4. Olódodo ní Olúwa:ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.
5. Kí gbogbo àwọn tí ó korìíra Síónì kí ó dààmú,kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.