Sáàmù 114:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Ísírẹ́lì jáde ní Éjíbítì,ilé Jákọ́bù láti inú ènìyàn àjòjì èdè

2. Júdà wà ní ibi mímọ́,Ísírẹ́lì wà ní ìjọba.

3. Òkun sì rí i, ó sì wárìrì:Jódáni sì padà sẹ́yìn.

4. Àwọn òkè ńlá ń fò bí agbo àtiòkè kékèké bí ọ̀dọ́ àgùntàn.

5. Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ òkun, tí ìwọ fi wárìrì?Ìwọ Jódánì, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn?

6. Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí agbo,àti ẹ̀yin òkè kékèké bí ọ̀dọ́ àgùntàn?

Sáàmù 114