Sáàmù 10:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ó wí fún ara Rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;Ó pa ojú Rẹ̀ mọ́ òun kì yóò rí i láéláé.”

12. Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ Rẹ̀ sókè, Ọlọ́run.Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.

13. Èeṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run?Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara Rẹ̀,“Kò ní pé mí láti ṣe ìṣirò”?

14. Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni o ri wàhálà àti ìrora;Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ Rẹ.talákà fara Rẹ̀ jin fún ọ;Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.

15. Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi;pèé láti wa sírò fún iwà ìkà Rẹ̀tí a kò le è rí.

Sáàmù 10