Òwe 9:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,ìmọ̀ nípa Ẹni mímọ́ ni òye.

11. Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùnọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.

12. Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”

13. Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo;ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláì ní ìmọ̀.

Òwe 9