Òwe 26:23-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Bí èédú lára ìkòkò, bẹ́ẹ̀ niẹnu tí ó mú ṣáṣá pẹ̀lú ọkàn búburú.

24. Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àsírí ara rẹ̀ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.

25. Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.

26. Ìkóríra rẹ le è farasin nípa ẹ̀tànṣùgbọ́n àsírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.

Òwe 26