Òwe 2:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. tí ó ní inú dídùn sí ibi ṣíṣetí ó sì ń yayọ̀ nínú àyídáyidà ibi,

15. ọ̀nà àwọn tí ó ṣe pálapàlatí wọ́n sì jẹ́ alérekérekè ní ọ̀nà wọn.

16. Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àgbèrè Obìnrinlọ́wọ́ aya oníwàkúwà àti àwọn ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀,

17. tí ó ti fi ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run.

18. Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikúọ̀nà rẹ̀ sì lọ sí ibi ẹ̀mí àwọn òkú.

19. Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padàtàbí tí ó rí ipa ọ̀nà ìyè.

20. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rerekí o sì rìn ní ọ̀nà àwọn Olódodo

21. Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náààwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà lórí rẹ̀

22. ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náàa ó sì ya àwọn aláìsòótọ́ kúrò lórí rẹ̀.

Òwe 2