Òwe 2:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ọgbọ́n yóò gbà ọ́ là kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú,lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ọrọ̀ ọ wọn jẹ́ àyídáyidà,

13. tí ó kúrò ní ọ̀nà tààràláti rìn ní ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn,

14. tí ó ní inú dídùn sí ibi ṣíṣetí ó sì ń yayọ̀ nínú àyídáyidà ibi,

15. ọ̀nà àwọn tí ó ṣe pálapàlatí wọ́n sì jẹ́ alérekérekè ní ọ̀nà wọn.

16. Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àgbèrè Obìnrinlọ́wọ́ aya oníwàkúwà àti àwọn ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀,

17. tí ó ti fi ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run.

18. Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikúọ̀nà rẹ̀ sì lọ sí ibi ẹ̀mí àwọn òkú.

19. Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padàtàbí tí ó rí ipa ọ̀nà ìyè.

20. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rerekí o sì rìn ní ọ̀nà àwọn Olódodo

21. Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náààwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà lórí rẹ̀

Òwe 2