Òwe 15:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyèṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.

5. Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọgbọ́n.

6. Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra,ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.

7. Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀;ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.

8. Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburúṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ẹ lọ́rùn.

9. Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburúṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.

Òwe 15